Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP Ní Ìlà Oòrùn Gúsù ti kìlọ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ láti má ka ìpè ipàdé pàjáwìrì àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ní Abuja sí.
Nínú àkọsílẹ̀ ìròyìn kan, alukoro ẹgbẹ́ ní ẹ̀ka ìlà oòrùn gusu, Chigozie Igwe, tẹnumọ pàtàkì ìṣọ̀kan láàrin ẹgbẹ́.
Ọ̀gbẹ́ni Igwe pariwo síta èròngbà àwọn kan láti dá rúkèrúdò sílẹ̀ nínú ẹgbẹ́.
Ó wá pàrọwà sì àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti má gba ẹ̀tàn láàyè kí wọn sì jẹ̀ olóòótọ sí àwọn adarí òdodo tẹ́lẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san