Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ NELFUND Bẹ̀rẹ̀ Pinpin Owó Àlàkalẹ̀ Ti Oṣù Kẹrin

171

Àjọ Nigerian Education Loan Fund (NELFUND) ti bẹ̀rẹ̀ pinpin Owó ẹ̀yá àlàkalẹ̀ ti Oṣù Kẹrin ọdún 2025 fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó peregede fún un jákèjádò Nàìjíríà.

Àkọsílẹ̀ láti ọdọ Alakoso àjọ Strategic Communications owó náà, Ìyáàfin Oseyemi Oluwatuyi,
jẹ kó di mímọ pé wọn ti ń pin owó náà fún àwọn tó yẹ ṣugbọn ìdíwọ́ díẹ̀ ma wà látàrí ẹ̀rọ wọn àti àwọn nǹkan ti wọ́n ń yanjú lọ́wọ́.

Ó sọ pé àwọn yóò san owó náà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lásìkò ní ọnà láti mú kí ètò ààrẹ – “Renewed Hope Agenda kẹ́sẹ jari.

Ó wá fi kun pé, àjọ náà mọ rírì sùúrù àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ bí ajọ NELFUND ṣe ń tèsíwájú láti mú kí ayé gbẹdẹmukẹ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button