Take a fresh look at your lifestyle.

Ọdún Egúngún Lágbayé Ti 2025: Makinde Pinnu Ìgbélárugẹ Àṣà Fún Àgbéga Ọrọ̀ Ajé

271

 

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti tẹnu mọ́ pé ìṣèjọba òun yóò máa ṣe atilẹyin fún ìmúgbòòrò àṣà àti ìgbélárugẹ ìṣẹ̀dálẹ̀ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Gómìnà ló síṣọ lójú ọ̀rọ̀ yìí níbi àṣèkágbá ọdún Egúngún Lágbayé ti ọdún 2025, ayẹyẹ to wáyé ni pápá ìṣeré Obafemi Awolowo to kalẹ sí agbègbè Òkè-Ado, ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

Gómìnà Makinde ẹni tí igbákejì rẹ̀, Bayo Lawal ṣójú níbi ayẹyẹ náà ló ṣàlàyé pé ìṣèjọba òun mú àṣà àti ìrìn àjò afẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan lára ọ̀pákútẹ̀lẹ̀ ètò tó là kalẹ lábẹ́ Omituntun 2.0, eléyìí tó pè ní Ọ̀nà sí Ìdàgbàsókè Ọlọ́jọ́ Pípẹ́, ọdún 2023-2027.

Gómìnà Makinde fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó ṣàlàyé pé ìṣèjọba òun fi ààyè gba onírúurú ẹ̀sìn eléyìí to mú kó ya ogúnjọ́ oṣù kẹjọ (August 20th) sọ́tọ̀ fún ọjọ́ Ìṣẹ̀ṣe tó sì fún gbogbo ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn to wù wọn ni ìbámu pẹ̀lú òfin Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

O wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àṣà àti ìrìn àjò afẹ́ kó ṣeé yà sọ́tọ̀, nígbà tó tẹnu mọ́ọ pé ọdún Egúngún jẹ́ ọ̀kan lára Àṣà àjogúnbá eléyìí tí ìjọba pinnu láti lò gẹ́gẹ́ bí ọ̀pákútẹ̀lẹ̀ fún ìmúgbòòrò ọrọ̀ ajé.

Makinde jẹ́ kó di mímọ̀ pé, ayẹyẹ tí ọdún yìí ni ẹlẹẹkeji irú rẹ̀ nínú èyí tí o fi ìdùnnú rẹ̀ hàn fún onírúurú ètò ti wọn ṣe àfihàn rẹ̀ àti bí Egúngún láti Orilẹ Èdè olómìnira Benin náà se kópa àti àwọn èèkàn láti Orilẹ Èdè Ghana, Brazil, Cuba àti àwọn ìlú miran lágbayé se wa ni ìkàlẹ̀ láti yẹ́ ètò náà sí.
O wá fi àsìkò náà ké sí gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn láti fojú sí ọ̀nà ti ayẹyẹ náà yóò fi máa pa owó sínú asunwọn ìjọba.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Alága ayẹyẹ náà, Ọba Rashidi Ladoja, ẹni tí Mayẹ Ìbàdàn, Olóyè Lekan Àlàbí gba ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ jẹ́ kó di mímọ̀ pé ayẹyẹ náà ní ipa pàtàkì lórí àṣà àti ohun àjogúnbá.

Alága ayẹyẹ náà wá fi àsìkò náà gbà ádùrá pàtàkì fún ìdàgbàsókè, ìlọsíwájú àti ìlọrọ̀ Ìlú Ìbàdàn àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọn, Komisana fún Àṣà àti Ìrìn Àjò Afẹ́ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, Ojo Abiọdun àti Ààrẹ Ọ̀jẹ̀ Parapò Lágbayé (Oje Parapò Worldwide), Ọmọ-ọba Adéọlá Adelakun lu Gómìnà Makinde lọgọ ẹnu fún ìṣèjọba ti kò láfiwé àti ọgbọ́n àtinuda to fi n gbé àṣà àti ìrìn àjò afẹ lárugẹ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nígbà tí wọn gba gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ náà kàn níyànjú láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba, kí wọ́n sì jìnnà sí ìwà jàgídí-jàgan eléyìí tí wọ́n mọ ọdún Egúngún sí.

Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀ ni Komisana fún Àṣà àti Ìrìn Àjò Afẹ́ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọmọwe Wasiu Olatunbosun ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Makinde fún ìkúnlápá to n ṣe fún ìgbélárugẹ àṣà àti ìṣe láti ìgbà tí ìṣèjọba rẹ̀ ti bẹrẹ iṣẹ́.

Olatunbosun wa fi àsìkò náà ṣàlàyé pé ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti n gbìyànjú láti gbé ìgbésẹ lójúnà àti jẹ́ kí ọdún Egúngún náà jẹ ọ̀kan lára ayẹyẹ UNESCO ti gbogbo àgbáyé náà yóò dá mọ̀, eléyìí tí yóò mú kí ọrọ̀ ajé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbèrú síi.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button