Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ifowopamọ ECOWAS Ti Ṣetán Láti Sí Ilè Ifowopamọ Si Orílè-èdè Cote d’voire.

240

Ilé Ifowopamọ ECOWAS fún ìdọ́kọ̀wọ̀ àti ìdàgbàsókè ti buwolu ìwé ajọṣepọ láti da ilé iṣé silẹ ni Orílẹ̀-èdè Cote d’Ivoire.

Ni ìlú Abidjah ni ọrọ àjọsọpọ tó dan mọ́rán yii wáyé láàárín ìjọba Orílẹ-èdè Cote d’Ivoire èyí tí Mínísítà fún òrò oke okun Ọ̀gbẹni Leon Jacob Adom sójú Orílẹ-èdè náà àti George Agyekum Donkor to sojú ilé ifowopamọ.

EBID jẹ ilé ifowopamọ ìdàgbàsókè to múlẹ gidigidi ní àwọn ìpínlẹ̀ mẹẹdogun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ilé Ifowopamọ ECOWAS wà fún ìdàgbàsókè àti láti mú ìdàgbàsókè bá àwọn ilé iṣé ìgbèríko dàgbà fún ìlọsíwájú.

Wọn ni látàrí sí sí ilè ifowopamọ tuntun Si Orílẹ̀-èdè Cote d’Ivoire èyí yóò tún mú irẹpọ, ìsọkan , àlàáfíà àti ìdàgbàsókè ba àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè náà.

Bákanáà wọn mú ààmì ẹyẹ fún Mínísítà fún ìdọ́kọ̀wọ̀ àti ìdàgbàsókè, Gómìnà EBID to sojú Orílè-èdè Cote d’Ivoire.

Nínú ọrọ rẹ Mínísítà àti Ààrẹ ilé Ifowopamọ EBID dupe púpò lówó ìjọba Orílẹ̀-èdè Cote d’Ivoire fun anfààní to fi gba wọn àti àtìlẹ́yìn rẹ.

Comments are closed.

button