Àjọ ẹlẹ́tọ̀ ìlera ti wọn pẹ ni West Africa Health Organizations (WAHO) tí fi ọjọ́ kun gbígbà abẹrẹ ajẹsara nípa àìsàn Lassa fever kàkà kiri àgbáyé.
Ní ìlú Abuja ni ọ̀rọ̀ náà ti jáde ni ọjọ́rú láti ẹnu ọ̀gbẹni Alábá Balogun tó jẹ alukoro fún ilẹ isé ìjọba fún ọ̀rọ̀ ìlera.
Wọn ní àwọn ni ìbáṣepọ̀ pèlú àwọn ilé iṣé ìlera míràn láti rí wí pé àwọn ènìyàn jẹ anfààní àbẹ́rẹ́ àjẹsára náà titi àìsàn náà yóò fi di ohun igbagbe.
Àwọn abánisepo náà ni ilé iṣé Corona Management service, Nigerian Health Watch, àti Bloom Public health.
Ìròyìn jade lásìkò ti wọn n ṣe ìpàdé ọdọọdún pẹlu àjọ ECOWAS.
Wọn ní àwọn o ri dájú wí pé àwọn ènìyàn kàkà kiri àgbáyé pata ni o n anfààní sí abẹ́rẹ́ àjẹsára náà.
Wọn ní àìsàn yíi jẹ ohun ti o léwu fún ìlera àwọn ènìyàn lágbayé kí àwọn àjọ ẹlẹ́tọ̀ ìlera lágbayé ma ṣe foju yẹpẹrẹ wó.