Take a fresh look at your lifestyle.

Ètò Ìlera Ọ̀fẹ́: Makinde Ṣíde Ìfilọ́lẹ̀ Ìlera Ọ̀fẹ́ Ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá/Ìlà-Oòrùn Ìbàdàn.

64

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti jẹ ko di mímọ̀ pé ìṣèjọba òun yóò tẹ síwájú láti máa pèsè ètò ìlera lójúnà àti ri dájú pé ará ìlú wa ni ìlera pípé eléyìí tí yóò mú kí ọrọ̀ ajé rú gọ́gọ́ síi, ti ìṣẹ yóò sì dínkù ni àwùjọ.

Makibde ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó n ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò ìlera ọfẹ Omituntun 2025 ni Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Ìlà-Oòrùn Ìbàdàn, níbi to ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìṣèjọba òun pinnu láti kọ́ àwọn ilé ìwòsàn Alábọ́dé ni gbogbo ẹkùn ìdìbò kí ètò ìlera bàa lè wà ni àrọ́wọ́tó ará ìlú.

Gómìnà Makinde, ẹni to ṣàlàyé pé ìṣèjọba òun ti ṣetán láti jẹ́ kí Ìpínlè jẹ́ àwòkọ́ṣe fún Ìjọba Àpapọ̀ eléyìí to pinnu láti kọ ilé ìwòsan Alábọ́dé ti kò dín ní 8,800 jákèjádò Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

Gómìnà Makinde nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti gùn le ṣíṣe ìgbédìde àti ìmúpadà bọ̀ sípò ilé ìwòsan Alábọ́dé ní àwọn ẹkùn ìdìbò 351 tó wà ni Ìpínlẹ̀ náà, nígbà tó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé níwọ̀n ìgbà ti ìgbésẹ yìí bá ṣeéṣe fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, kò ní ṣòro fún ìjọba Àpapọ̀ láti ṣe àgbékalẹ̀ irú ètò bẹẹ.

Gómìnà wá fi àsìkò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ṣe ojúṣe wọn lójúnà àti ri pe èròngbà náà fìdí múlẹ ni agbọn ètò ìlera.
Makinde gbe òṣùbà káre fún Ọ̀jọ̀gbọ́n Temitope Alonge àti Onímọ̀ ìṣègun Òyìnbó Muideen Olátúnjí fún iṣẹ takutaku ti wọn ṣe lati mú kí ètò náà fìdí múlẹ.

Bákan náà ni Gómìnà fi àsìkò náà gbé òṣùbà káre fún Komisana fún ètò ìlera ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Dókítà Oluwaserimi Ajetunmobi, Alága Àjọ to n mójú tó ilé ìwòsan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Oyo State Hospital Management Board), Dókítà Akin Fagbemi àti gbogbo àwọn Akọwe àgbà ni ile iṣẹ́ ìjọba tó n rí sí ìpèsè ètò ìlera àti gbogbo òṣìṣẹ́ elétò ìlera pátá.

Bẹẹ náà ni Gómìnà Makinde fi àsìkò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Ìlà-Oòrùn Ìbàdàn fún àtìlẹ́yìn wọn àti gbogbo ènìyàn rere Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún iṣẹ rere wọn eléyìí to mu ki ìṣèjọba rẹ̀ máa ni àkọsílẹ àṣeyọrí rere.

Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀, Komisana fún ètò ìlera, Dókítà Ajetunmobi dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Gómìnà fún ìdúró ṣinṣin lórí ìpinnu rẹ̀ láti mú ìgbéga dé bá ètò ìlera nipasẹ ìpèsè àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera àti àwọn ohun èlò amayederun láti mú kí ojú iṣẹ́ máa yá.

Ajetunmobi wá ṣàlàyé síwájú sí pé ètò ìlera ọfẹ Omituntun yìí ni yóò máa wáyé ni ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé ní ọjọ́ mẹ́ta fún ìpèsè ètò ìlera tó péye àti láti ṣe àyẹ̀wò lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ fún gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

O wá tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó sọ pé ìjọba ti n gbìyànjú láti ṣe ìforúkọsílẹ àwọn tó n jẹ anfààní ètò ìlera adójútòfò ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Oyo State Health Insurance Scheme, OYSHIA) lójúnà àti máa pèsè ètò ìlera fún gbogboògbò.

Komisana wa fi àsìkò náà rọ gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ náà kàn láti ṣe nọmba (service codes) wọn lọ́jọ̀, ki wọn sì rí dájú pé wọn tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn dókítà.

Dókítà Akin Fagbemi wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà fún bo se gba àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera sí àwọn ilé ìwòsàn ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, eléyìí tó mú kí wọ́n fi ontẹ lu ẹka to n ri sì tito egungun ara (Physiotherapy).

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button