Àjọ tó n mójú tó ọrọ oúnjẹ àti ògùn ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NAFDAC ) tí gbèsè le ilé iṣé olómi kan ni ìpínlẹ̀ Nasarawa léyìn ìgbà ti wọn kófìrí wí pé wọn Oka ojú òṣùwọ̀n to.
Ọ̀gbẹni Anga Emmanuel to jẹ igbákejì àjọ NAFDAC ló sọ èyí di mímọ̀ ni ọfisi wọn ní ọjọ́ ẹtì, lásìkò to n ba àwọn oníròyìn sòrò.
Ó ni ilé iṣé náà ko ni ìwé àṣẹ láti bẹrẹ oja, pàápàá jùlọ àjọ NAFDAC ko mọ sí ilé iṣé náà nitori wọn kò sí nínú ìwe àkọsílẹ̀ àwọn tó Kanu òṣùwọ̀n lati pase omi.
Wọn ní àṣírí yìí tu lásìkò tí wọn ṣe ìbẹ̀wọ̀ sí àwọn ilé iṣé káàkiri nibe ni won ti rí wí pé wọn n pase omi ni ọna ẹ̀bùrú
Ó ní Ọgbẹni Christian Chukuma ti wọn nawo ga lásìkò náà láti fà le ofin lọwọ.
Ọgbẹni Emmanuel ni orúkọ àwọn omí ti ko tana náà ní, Bilal table water, Nkonjun table water, Anumzi table water àti Agbeni Table water kí àwọn ènìyàn sa fún àwọn omí ni mímú nitori kò dára fún ìlera ará.
Ó ní àwọn ko ni deyin láti wa ṣe àwọn àtúnṣe yìí sí Orílẹ-èdè Nàìjíríà ki ìjàmbá ba le di ohun igbagbe lori ọ̀rọ̀ oúnjẹ.