Ọ̀nà Àbáyọ Si Ìdájọ Òdodo Àti Ìpẹ̀tù Sí Aáwọ̀: Aláàfin Ọ̀yọ́ Pé Fún Ìbáṣepọ̀ Láàrin Àṣà Yorùbá Àti Ìṣèjọba Òde Òní
Aláàfin ti Ìlú Ọ̀yọ́, Ọba Akeem Abímbólá Owoade I ti tẹnu mọ́ pé òun dúró digbí lórí èrò rere tí òun ni fún àwọn èniyàn Ìlú Ọ̀yọ́ àti ilẹ Yorùbá.
Ọba Owoade , ẹni tó sọ di mímọ̀ pé ọ̀nà kan gbòógì láti mú àdínkù dé bá ìpèníjà to n kojú ìdájọ òdodo àti ìpẹ̀tù sí aáwọ̀ ní láti jẹ́ kí ìbáṣepọ̀ wà láàrin ìwà ọmọluwabi eléyìí tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìṣàkóso ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá àti ìlànà ìṣèjọba ti òde òní.
Ọba Owoade ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde lásìkò tó gba àlejò àwọn Ọba ìlú àtí agbègbè Ìbàràpá tí wọn ṣe àbẹ̀wò síi ni Ààfin.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí Alàkóso ìròyìn àti ìkéde fún Aláàfin Ọ̀yọ́, Bode Durojaiye fi síta ṣe ṣàlàyé pé, Ọba Owoade jẹ́ kó di mímọ̀ pé òun gẹ́gẹ́ bíi adarí àti ògúnná gbòngbò ni láti dúró bíi okùn tó n so àṣà ilẹ̀ Yorùbá àti ìṣèjọba òde òní papọ̀, nígbà tó fii kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ipò Aláàfin jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbélárugẹ àṣà, ìṣọ̀kan àti ohun àjogúnbá ilẹ̀ Áfíríkà tí yóò dúró láéláé.
Ọba Owoade wá fi àsìkò náà pé fún irúfẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ eléyìí tí Aláàfin to wàjà, Ọba Lamidi Adéyemí III jẹ anfààní rẹ̀ láti ọdọ àwọn ọba náà, tó sì ṣèlérí fún gbogbo wọn pé òun yóò gbìyànjú láti tẹ̀lé ipasẹ̀ Ọba Adéyemí III.
Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Olú Igbo-Ọra, Ọba Jimoh Olajide Titiloye, Asoroolu Ayinla V, tó léwájú àwọn ọba yòókù láti ṣe abẹwo sí Aláàfin jẹ́ kó di mímọ̀ pé, àwọn ní ìgboyà pé ọgbọ̀n, ìdarí, àti ìfọkànsìn Ọba Owoade ni àsìkò tó gorí Àpèrè Aláàfin yóò túbọ̀ mú ìṣọ̀kan àti ìlọsíwájú dé bá Ilú Ọ̀yọ́, Ilẹ̀ Yorùbá àti Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà lápapọ̀.
Abiola Olowe
Ìbàdàn.