Ẹ ṣàpọ́nlé ìṣẹ̀ǹbálẹ àwọn agbègbè tí ó gbà yín lálejò-Adarí gbogbogbòò Àgùnbánirọ̀
Eyitayó Fauziat Oyetunji
Adarí gbogbogbòò fún àwọn Àgùnbánirọ̀ (NYSC), Ajagun Olakunle Nafiu, ti gba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Àgùnbánirọ̀ nímọ̀ràn láti ṣàpọ́nlé ìṣẹ̀ǹbálẹ àwọn agbègbè tí ó gbà oníkúlukú wọ́n lálejò kí wọn ó sì jọ gbépọ̀ pẹ̀lú irẹ́pọ̀.
O sọ eyi di mimọ lasiko ti o n ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa sọrọ ni ibugbe ti wọn n ko wọn si lati kọkọ ṣe idanimọ ilu, ni Wailo, ipinlẹ Bauchi ati ti ipinlẹ Plateau, ni Doi-Du, ni ijọba ibilẹ agbegbe Gusu Jos.
O ni gbogbo ẹkun Naijiria ni ọlọrun kẹ pẹlu eto iṣẹnbalẹ loriṣiriṣi, eyi ni o faa ti eniyan fi nilo lati kọ wọn, mọ wọn, ati lati kọ nipa iṣẹnṣe awọn eniyan miran, ti o si fi kun un pe ko si eyi ti o dara ju ọkan lọ.
O wa kilọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ Agunbanirọ lati maa mura daradar, paapaa julọ nigba ti wọn ba wa ninu aṣọ idanimọ Agunbanirọ NYSC. O sọ pe gegẹ bi ẹni ti o ti kawe gboye, wọn ni lati maa mura boṣe tọ ati bo ṣe yẹ, ki wọn fi le ri apọnle.