Orílè-èdè Sudan ti so yìgì tó le pẹ̀lú orílè-èdè United Arab Emirates (UAE) àti pé o ti mú àwọn Àm̀básédọ̀ rẹ̀ kúrò níbẹ̀.
Mínísítà ètò ààbò, Yassin Ibrahim Yassin fi ẹ̀sùn kan Abu Dhab pe ó ń tàpá si òfin Sudan nípasẹ̀ ọmọ ogun – “Rapid Support Forces (RSF) militia”.
Ọ̀gbẹ́ni Yassin sọ pé ìgbésẹ náà wáyé kíá látàrí pé ọmọ ogún UAE ń sàtìlẹyìn fún àwọn RSF, bíi pipèsè ohun ìjà ogun ojú Òfúrufú tí wọ́n lò laipẹ yii lórí oju omi, Papakọ̀ òfurufú àti ẹka apínánká orilẹ̀-ède Sudan.
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé tilẹ̀ sọ pé o ju ìlàjì ènìyàn ilẹ̀ Sudan tó súnmọ́ Àádọta Mílíọ̀nù, bíi Mílíọ̀nù màrúndínlọ́gbọ̀n ló nílò ìrànlọ́wọ́ ní kíámọ́sá, ìyàn sì ti wà ní ọ̀pọ̀ ibi bí Darfur.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san