Ìrìn Àjò Sí Ilẹ̀ Mímọ́ Hajj: Gómìnà Makinde Rọ Àwọn Arìnrìn Àjò Láti Gbàdúrà Fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Àti Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ṣèlérí pé gbogbo ọmọ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó bá fẹ́ rin ìrìn àjò Hajj ni ọdún 2026 ni yóò máa gbéra láti Pápákọ̀ òfurufú Ladoke Akintola tó wà ní agbègbè Alakia ní ìlú Ìbàdàn tààrà lọ sí ilẹ̀ Sáúdí Arábíà.
Gómìnà, ẹni tó fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lásìkò tó n ṣe ẹ̀yẹ ìdágbére fún arinrin àjò sí ilẹ̀ mímọ́ Hajj lo ké sí gbogbo wọn láti gbe ohùn ádùrá sókè fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, nígbà tó tún rọ̀ wọ́n láti jẹ́ aṣojú rere fún Ìpínlẹ̀ wọn.
Ayẹyẹ ìdágbére náà lo wáyé ní Hajj Camp to wa ni agbègbè Olodo ní ìlú Ìbàdàn, tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

Gómìnà fi àsìkò náà ṣàlàyé bi iṣẹ́ ṣe nlọ lójúnà àti jẹ́ kí Pápákọ̀ òfurufú náà dà bíi ti ilẹ̀ òkèèrè, nígbà tó fi kún pé mímú àgbéga dé bá Pápákọ̀ òfurufú náà yóò mú kí ọrọ̀ àjé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ru gọ́gọ́ síi.
Gómìnà wá tẹnu mọ́ pé, anfààní to pọ̀ ní yóò jẹ́ fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti àwọn arìnrìn àjò sí ilẹ̀ mímọ́ Hajj ba gbéra láti Pápákọ̀ òfurufú Ladoke Akintola tààrà lọ sí ilẹ̀ Sáúdí Arábíà nítorí ìjọba àpapọ̀ yóò fi àwọn òṣìṣẹ́ Aṣọ́bodè àti òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ to n ri sì wíwọlé àti ìjáde lọ sí ilẹ̀ òkèèrè ṣọwọ́ sí Pápákọ̀ òfurufú náà.
Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀, Alága ìrìn àjò sí ilẹ̀ mímọ́, ẹka ti àwọn Mùsùlùmí, Sheikh Atere fi àsìkò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Makinde fún iṣẹ́ ìdàgbàsókè eléyìí to lààmì-laaka àti ìkúnlápá to n ṣe fún àwọn Mùsùlùmí láti ri dájú pé ìrìn àjò Hajj ti ọdún 2025 wáyé pẹ̀lú ìrọ̀rùn.
Sheikh Atere fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Gómìnà, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti gba ìwé ìrìnnà fún gbogbo àwọn arìnrìn àjò ti wọn yóò sì máa gbéra lọ ní ìpín méjì ní ọjọ́ Kẹwàá (10/05/2025) àti ọjọ́ kọkànlá (11/05/2025) oṣù kàrún ọdún yìí. O wá tún fi kún pé, ìgbìmọ̀ to n ri sì ìrìn àjò Hajj ti pèse ilé gbèé àti àwọn ohun míràn tí yóò mú kí ìrìn àjò náà rọrùn.
Nígbà tó n da àwọn arìnrìn àjò lẹkọọ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Kamil Koyejo Oloso gba gbogbo wọn níyànjú láti kọjú sí ohun tí wọn bá lọ, ki wọn sì máṣe ná owó ní iná àpà, kí wọ́n sì máa wá ọmọnìkejì wọn.
Abiola Olowe
Ìbàdàn