Ikọ̀ Ikorodu City pakítí mọ́lẹ̀ ní ilé wọn láti lu Ikọ̀ Bayelsa United FC ní àlùbami ẹ̀wà ní ayò Mẹ́ta sí Méjì (3-2) ní ọjọ́ Ọ̀jorú níbi ìdíje alárinrin náà.
Ìdíje ọdún 2024/2025 Nigeria Premier Football League (NPFL) ti ọjọ́ kẹrìndínlógójì ní wọn gbà ní pápá iṣere Mobolaji Johnson Arena, ìlú Èkó.
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin agbábọ́ọ̀lù Ọ̀gá ló kọ́kọ́ ṣíṣe ayò gbígbá wọlé ní ìsẹ́jú méjì àkọkọ láti ọdọ Okechukwu Nwanna to forí gbé bọ́ọ̀lù ti Balógun ikọ̀ rẹ, Waliu Ojetoye sọ síi.
Ikọ̀ Bayelsa United dáa padà ní iṣẹ́jú mọ́kànlá nígbà ti golí Oluwadamilare Aina se àsìse.
Ikọ̀ Ikorodu tún gbá bọ́ọ̀lù Kejì wọlé láti ẹsẹ̀ Oyedokun tí Golí alátakò wọn, Clinton Ezekiel kòsì leè mu.
Ikọ̀ Bayelsa United tún dáa padà ní iṣẹju mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nígbà ti Auwal Sadiq forí gbé bọ́ọ̀lù wọlé. Ayò wá di méjì sí méjì (2-2).
Ikọ̀ Ikorodu tún gba bọ́ọ̀lù miran wọlé ní iṣẹju mẹ́tàlélọ́gbọ̀n láti ẹsẹ̀ Tosin Adelani sùgbọ́n olùrànlọ́wọ́ Rẹfírí sọ pé offside ni, wọn kò sì kàá. Sùgbón ní abala Kejì, Shola Adelani fi orí gbé bọ́ọ̀lù ti Austin gba wọlé ló wá yọrí si ayò mẹ́ta sí méjì (3-2) lẹ́yìn ti akọ́nimọ̀ọ́gbá, Nurudeen Aweroro ti yọ àwọn agbabọ́ọ̀lù kan tó sì fi Ayomide Cole àti Moses Shodeinde rọ́pọ̀ wọn
Akọnimọọgba Bayelsa United, Dare Ogundare sọ pé àwọn nígbàgbọ́ pé àwọn yóò gbá ọ̀mìn, sùgbọ́n kò ṣeéṣe, ó wá gbóríyìn fún ikọ̀ agbabọ́ọ̀lù rẹ̀ pé wọ́n gbìyànjú bótilẹ̀ jẹ́pé wọ́n fìdí rẹmi.
Ikorodu City FC ti wá bọ́ sì ipò kẹrin lórí àkàbà ìdíje NPFL pẹ̀lú àmì mẹ́rìndínlọ́gọ̀ta nínú ìdíje mẹ́rìndínlógójì, wọ́n ti borí ìdíje mérìndínlógún, wọ́n gbá ọ̀mìn méjọ, wọ́n fìdí rẹmi ní ìgbà méjìlá.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san