Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Plateau tí ṣé àṣeyọrí ńláǹlà nínú gbígbógun tí ìwà ọ̀daràn, tí wọ́n sì gba òun ìjà tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ́wọ́ wọ́n lákòókò tí wọ́n yabo ibùdó àwọn ọ̀daràn kán ní ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Jos.
Kọmisana ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ náà, Emmanuel Olugbemiga Adesina, ló sọrọ yìí lásìkò tó n bá àwọn akọroyin sọrọ ní ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà nílùú Jos, olú-ìlú ìpínlẹ̀ náà.
![]()
Gẹ́gẹ́ bí CP Adesina, alẹ́ ọjọ́ kẹ́rin oṣù kàrún, ọdún 2025 ní ikọlù náà wáyé ní nnkan bii aago mẹsán alẹ́ lẹ́yìn ìtanilólobó kán.
Comments are closed.