Hajia Maryam Olabisi Yusuf tó jẹ Ìyá Olùdarí Ìròyìn Ayélujára tí Ilè Akéde Nàìjíríà (VON), Hajia Sani, tí jáde láyé ní Ìlu Abùjá, Olúìlú Orílẹ̀-èdè yìí, tí wọ́n sí sìn ní ìlànà Islam ní Ilú Ilorin, Olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Kwara.
Olóògbé Hajia Maryam ní wọ́n gbé lọsí ìtẹ lẹ́yìn ádùrá ‘Janazah’ tí ‘Imam’ tí Idi-Ape, Imam Salihu Ibn Bashar ṣé olórí.

Ṣáájú, Imam àgbà tí tí ìjọ ‘Ansarudeen’ tí Nàìjíríà, Shaikh Muhammad Shafi’i àti àwọn àlùfáà Islam mìíràn ṣé àkànṣe ádùrá pàtàkì kán fún ìsinmi ẹmi tí olóògbé, ó ṣé àpèjúwe ikú gẹ́gẹ́bí èyítí kó ṣée sá fun tàbí kọ̀ fún gbogbo ẹmi.

Olóògbé Hajia Maryam Yusuf kú ní kùtùkùtù òní ní ile-iwosan ‘Family Care Multi Clinic’ ní Abuja ní ẹni ọdún mọkandinlọgọrin (79).


Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ, ọmọ-ọmọ àti àwọn ọmọ-ọmọ-ọmọ ní won gbẹyin olóògbé. Sún ùn re ọ!
Comments are closed.