Take a fresh look at your lifestyle.

Bournemouth Yá Arsenal L’ẹnu Nígbàtí Aston Villa Ń Tẹ̀síwájú Lórí Tábìlì ‘EPL’ ‎

Lekan Orenuga

117

Bournemouth bóri Arsenal fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìdíje ilẹ́ Gẹ̀ẹ́sì ‘English Premier League’ ní Ọjọ́ Sátidé (Àbámẹ́ta), àti pé ìkọ náa túnramú ní ìdàkejì ìfẹ́sẹwọ́nsẹ́ ná èyí tó yá àwọn ènìyàn l’ẹ́nu bí wọ́n ṣé bóri pẹ̀lú ayo méjì sí ẹyọ kan (2-1).

‎ Aston Villa náà lú Fulham 1-0 látí tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìrètí látí kópa nínú ìdíje Yúrópù (UEFA Champions League), ní sáà igba-bọọlu tó mbọ.

‎Leicester City náà bóri ẹlẹgbẹ wọ́n Southampton ní 2-0 bí wọ́n tí ṣé pàdánù eré ifẹsẹwọnsẹ mẹsán wọn.

‎ Everton àti Ipswich Town náà tá ọmì 2-2 bí ìkọ Everton ṣé n dagbere sí ‘Goodison Park’.

‎ Pàdà sí pápá ìṣèré Emirate, àwọn igbaradi Arsenal fún ẹ̀ṣẹ Kejì idije Yúrópù ìyẹn ‘UEFA Champions League’ pẹ̀lú Paris St Germain ní ọjọ́rú jọ bí wípé òun ló k’oba wọ́n, bí wọ́n ṣé pàdánù ifẹsẹwọnsẹ eyi ti wọ́n tí n bóri ni ìdá àkọkọ́.

Comments are closed.

button