Take a fresh look at your lifestyle.

SGF Gba Àwọn Adarí Ẹ̀sìn Níyànjú Láti Ní Ẹ̀mí Ìpamọ́ra Àti Ìṣọ̀kan Fún Orílẹ̀-èdè

109

Àti Ìṣọ̀kan Fún Orílẹ̀-èdè
Akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (SGF), George Akume Abuja ti rọ àwọn olórí ẹ̀sìn láti darapọ̀ mọ́ ìjọba àpapọ̀ ní ọ̀nà láti so ètò ààbò lé dain-dain àti kí wọn sì wà ní ẹ̀mí ìṣọ̀kan pẹ̀lú ètò ìrètí ọ̀tun ààrẹ Ahmed Tinubu.

Ó tún gbosuba fún ààrẹ Tinubu pé ètò ààbò ti dára síi lẹ́yìn tí ó ti gorí àlééfà. Ó tún dúpẹ lọ́wọ́ ìjọba látàrí akitiyan wọn láti gbógun ti àwọn onísumọ̀mí àti ìjà agbègbè.

Ní tirẹ̀, Bísọ́ọ̀bú àgbà, John-Praise Daniel, dúpẹ lọ́wọ́ ààrẹ Tinubu fún gbígbé ilé ẹkọ gíga Fáfitì ìmọ̀-Sáyẹ̀nsì ti- University of Applied Science ni Kachia, gúsù kaduna wá sí ìlú náà .

Ó tún gbósùbà fún igbiyanju ìjọba fún ìtèsíwájú ọrọ̀ ajé, ọnà láti jẹ kí ètò ààbò fẹsẹ̀ rin lẹ̀ èyí tó ti jẹ́ kí irè oko dára síi, eléyìí tó jẹ kí owó ti wọn fi ń ra ounjẹ wálẹ̀

Àbẹwò náà pari pẹlu ádùrá fún àṣeyọrí ìjọba ààrẹ Tinubu àti ìtèsíwájú orílẹ̀-èdè.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button