Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Nàmíbíà Ri Àrídájú Àjàkálẹ̀ Àìsàn Ẹṣin Adúláwọ̀

136

Ẹ̀ka tó wà fún ìtọjú àwọn ẹranko orílẹ̀-èdè Nàmíbíà ti kéde àjàkálẹ̀ àìsàn ẹṣín ilẹ̀ Adúláwọ̀ – “African horse sickness”, wọ́n sì ti kófí àìsàn nàá lára márùndínlọ́gbọ̀n ènìyàn níbi ẹ̀ka ti ń mójú tó àwọn ẹranko ní agbègbè Otjinene, Windhoek, Okahandja, Omaruru, Gobabis, àti Mariental.

Adelé ọ̀gá àgbà ẹ̀ka ti ọgbà ìtọ́jú àwọn ẹranko, Johannes Shoopala sọ èyí fún àwọn ènìyàn ní ọjọ́ Ẹtì àti pé ètò láti má jẹ́ kí àìsàn nàá tànká ń lọ lọ́wọ́.

Bí Shoopala se sọ, ọjọ́ ti wọn yàn fún àwọn ènìyàn láti lọ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára bẹ̀rẹ̀ ní ilé Namibia láti ọjọ́ kínní oṣù kẹfà títí di ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá.

Àìsàn nàá jẹ àìsàn ti kí tá mọ́ni ti eṣinṣin kékeré oníwo méjì ń kó káàkiri lọ sí ọ̀dọ̀ eranko bíi ẹṣin, Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ẹranko ti òyìnbó ń pè ní Zebra abbl.

Àmì ti ẹni tó bá ń ṣe máa ri ní wípé, yóò sòro fún láti mín dáradára, ikọ́, ibà, ìlàágùn, ikun láti imún; ìdá kíkú ẹlẹ́mìí leè lọ sókè bí idà àádọ́rin ninu Ọgọ́rùn- ún.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button