Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò Ọdún 2027: Ẹgbẹ́ Òṣèlú Labour Party Kòní Darapọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ Mìíràn

135

Ẹgbẹ́ Òṣèlú Labour Party ti sọ pé àwọn koni darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ míràn ninu ìbò gbogbogbòò ọdún 2027.

Èyí jẹ ọkan lára kókó méjìlá àlàkalẹ̀ ìpinnu níbi Ìpàdé National Executive Council (NEC) ti wọn ṣe ní ọjó Ẹtì ní ìlú Abuja.

Nigba ti o ń kàá, alága àpapọ̀ ẹgbẹ́, ọ̀gbẹ́ni Julius Abure sọ pé ẹgbẹ́ kòní darapọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ miran kankan fún ìgbáradì ìdìbò 2027.

Kàkà bẹẹ, ẹgbẹ yóò wà ọnà láti ṣe àtúnṣe sí ẹgbẹ, àtúngbéyẹ̀wò, ètò àti aba ìtèsíwájú tuntun ní àwọn yóò ṣeé láti bori ninu ìbò tó ń bọ, Abure sọ èyí.
Ènìyàn tí kò leè to ẹgbẹ́ wọn kò leè se adarí fún ẹgbẹ́ àjùmọ̀ṣepọ̀.”

Ní ti ipò gómìnà ọdún 2025 ìpínlẹ̀ Anambra, Abure fi dá àwọn ènìyàn lójú pé Olóyè George Moghalu ti làlùyọ bi olórí tó gbé àsìá ẹgbẹ́ sókè tí wọ́n dìbò yàn nínú ìbò àkọ́bẹ̀rẹ̀ kòmẹsẹ̀óyọ tó wáyé ní ọjó karùn ún oṣù kẹrin ní ìlú Akwa.

Àjọ NECsi ti kí olóyè Chief George kú oríire, wọ́n sì ti ní kí gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ àti Ndi Anambra gbárùkù tìí nínú ìbò ọjọ́ kẹjọ oṣù kọkànlá tó n bọ̀ fún ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Anambra, ó sọ èyí.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button