Take a fresh look at your lifestyle.

Ìṣòro Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP Kọjá Sísákiri Lọ Ẹgbẹ́ Míràn -Sénétọ̀ Maidoki

158

Amòfin ìjọba àpapọ̀ kan, Sẹ́nétọ̀ Garba Maidoki (PDP–Kebbi) ti sọ pé bí àwọn ènìyàn ṣe ń sá kúrò nínu ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) kò ṣe ẹ̀yìn ìṣòro inú ilé tó ń bá ẹgbẹ fínra tó n lọ lọ́wọ́.

Ọ̀gbẹ́ni Maidoki níbí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú Abuja sọ pé lílọ ọmọ ẹgbẹ́ láti PDP lọ sí ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) tó ń se àkóso lọ́wọ́ kò dára, ẹgbẹ́ kan soso kò dára fún ìjọba àwarawa.

Ẹni tó sojú fún agbègbè gúsù Kebbi, Maidoki kẹ́dùn bíi àwọn ènìyàn se ní ya lọ kúrò ninú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, pé fún ìpàdé gbogbogbòò ẹgbẹ. Àwọn adarí ẹgbẹ́ níláti tètè gbé ìgbésẹ kó tó pẹ́jù.

Nígbà ti wọn béèrè bóyá òun náà yóò kúrò nínú ẹgbẹ́ láìpẹ́, ó sọ pé àfojúsùn òun dá lórí ànfààní àpapọ̀ ti gbogbo ènìyàn àti pé kí ṣe anfààní òun nìkan, kii ṣe ìmọ̀ tara òun nìkan rárá.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button