Alága Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Ìpínlẹ̀ Kebbi, Abubakar Muhammad Kana ti ṣẹ́ àhesọ lórí ẹ̀rọ ayélujára pé Gómìnà Nasir Idris fẹ́ sálọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú míràn.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi Ìpàdé alẹ́nulọ́rọ̀ ẹgbẹ́ APC kan ti gómìnà náà sì wa ni ìkàlẹ̀, igbákejì rẹ̀, Gómìnà tẹ́lẹ̀rí, Dakingari àti Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, Kana sọ àrídájú pé ipinlẹ yóò máa ṣògo lábẹ́ ìdarí ìjọba ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti gómìnà Idris ń darí.
Gómìnà Idris sọ nínú ọrọ rẹ pé kó sì òtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ pé òun fẹ kúrò lọ sí ẹgbẹ́ míràn, wọ́n fẹ sí àwọn ènìyàn lọ́nà ní. O ní òun gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àti wípé òun ní ìgbàgbọ́ nínú ìjọba òun.
Àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ nínú ẹgbẹ́ APC náà sọ pé àwọn nígbẹkẹ̀lé nínú ìṣèjọba ààrẹ Tinubu àti Gómìnà Idris, àti pé àwọn yóò ṣiṣẹ́ tọ ìdàgbàsókè ẹgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà àti ìjọba rere ti yóò mú kí ẹgbẹ́ náà tún ṣe ìjọba síi lẹ́ẹ̀kejì.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san