Take a fresh look at your lifestyle.

Akọrin Ọmọ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Kan Kú Sínú Ìjàmbá Iná Inú-ilé

214

 

Jill Sobule, gbajúmọ̀ akọrin, olùkọrin-sílẹ̀ Ọmọ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti wọ́n mọ̀ nípa àkọlé orin rẹ̀ – “LGBTQ+ hit “I Kissed a Girl,” ti ku sínú Ìjàmbá iná inú-ilé ní Woodbury, Minnesota.

Akéde orin ló fi ìròyìn ikú rẹ̀ léde bótilẹ̀-jẹ́pé òkùnfà iná náà kòyé ẹnikẹ́ni. Olùkọ́ni rẹ̀, John Porter, sọ pé àdánù nlá ní ikú rẹ̀, orin rẹ̀ tilẹ̀ ti wọnú àṣà wa.
“Oríire ló jẹ fún òun pé òun ń bá ṣiṣẹ́ pọ̀, mo pàdánù alabaṣiṣẹpọ̀ àti ọ̀rẹ́ lónìí. Mo nígbàgbọ́ pé orin rẹ̀, ìrántí rẹ̀ àti ogún tó fi sílẹ yóò ràn ọpọ ènìyàn lọ́wọ́”, o fi kun.

Sobule yẹ kó seré ní Denver sugbon èyí ní yóò wà jẹ iranti fún ayé rẹ. Ètò iranti fún yóò wáyé ní igbà ọ̀dá kí ọdún tó parí.

Láàrin ọgbọ̀n ọdún tó fi ń ṣeré, ó gbé àwo orin méjìlá síta. Lára wọn ní; “death penalty, anorexia nervosa, reproductive rights, and LGBTQ+ issues”. Àwo rẹ àkọ́kọ́,“Things Here Are Different,”ni o gbé jáde ní 1990.

Wọn bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù kínní ọdún 1959 ní Denver, Colorado, Sobule kọrin pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ bíi ; Neil Young, Cyndi Lauper, àti Billy Bragg. Kí Olúwa tẹ sì afẹfẹ rere.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button