Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Ìpínlẹ̀ Cross Rivers ti pààrọ̀ òfin ètò ìlera ti odún 2002 pẹ̀lú òfin tuntun ti ọdún 2025 lójúnà àti ní ìkóyawó àti ìkẹ́ṣẹjárí òfin ètò ìlera
Ọ̀gbẹ́ni Hillary Bisong, tí ó n sójú ẹkùn Boki 2 ni ó se agbátẹrù àbádòfin náà èyí tí ó wáyé ní ọjọ́ kejìlá osù kẹsàn-án ọdún 2024, tí iṣẹ́ sì ń tẹ̀síwájú lórí rẹ̀
Ìròyìn fi yéwa pé gbogbo àwọn ọmọ Ilé Asòfin ni ó fi ọwọ́ sí àbádòfin náà nítorí pàtàkì rẹ tí ìrètí sì wà pé yóò mú ìtẹ̀síwájú bá ètò ìlera, tí yóò sì dá iṣẹ́ sílẹ̀ fún ará ìlú