Gómìnà Muhammadu Inuwa Yahaya ti Ìpínlẹ̀ Gombe ti sàfirinlẹ̀ èròńgbà ìsèjọba rẹ̀ láti mójútó ìgbáyégbádùn àwọn òsìṣẹ́ ní Ìpínlẹ̀ náà Gẹ́gẹ́ bí pọ̀pọ̀sìsì àyájọ́ òsìṣẹ́ se ń lọ lọ́wọ́
Gómìnà kí àwọn òsìṣẹ́ kú oríire látàrí àyájọ́ àwọn òsìṣẹ́ ti àgbáyé , ti ọdún 2025, ó lùwọ́n lọ́gọ ẹnu fún ipa ribiribi tí wọn ń se fún ìdàgbàsókè àti ìtẹ̀síwájú Ìpínlẹ̀ Gombe
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àyájọ́ Òṣìṣẹ́, Gómìnà Yahaya sàpèjúwe àwọn òsìṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ àti alátìlẹyìn fún ìsèjọba rere ní Ìpínlẹ̀ Gombe, ó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti tẹ̀síwájú nínú ojúse rẹ̀ fún ìpèsè ohun èlò àti amáyédẹrùn fún àwọn òsìṣẹ́