Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Anambra Ṣègbékalẹ̀ Ẹgbẹ́ Imọlẹ̀ Ìṣọ̀kan Ìdárayá

Lekan Orenuga

112

Gómìnà Chukwuma Soludo tí ṣé ìfilọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ imọlẹ̀ ìṣọ̀kan ìdárayá ní Awka ní ìpínlẹ̀ Anambra, gẹ́gẹ́ bí ará ètò eré ìdárayá tí orílẹ̀-èdè ikejilelogun, èyí tí wọ́n pé ní ‘Gateway Game,’ tí yóò wáyé ní Ìpínlẹ̀ Ogun látí ojọ́ kẹ́rindínlogun oṣù karùn-ún sí ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù karùn-ún ọdún yìí.

‎ L’àkókò ayẹyẹ kán ní Ilè Ìjọba ní Awka, àwọn aṣojú kán látí Ìgbìmọ̀ Àwọn eléré ìdárayá tí Orílẹ̀-èdè (NSC) tí gbé imọlẹ̀ ìṣọ̀kan ìdárayá náà fún Gómìnà Soludo, tí Olóye Chinedu Nwoye Glamour, Alàkóso Ìpínlẹ̀ jẹ́ aṣojú fún.

‎ Nínú àwọn ọrọ rẹ̀, Gómìnà Soludo gbóríyìn fún NSC fún ipá pàtàkì rẹ̀ ní ìgbéga àlàáfíà àti ìsọkan orílẹ̀-èdè nípasẹ àwọn eré ìdárayá.  O tún tẹnumọ pé Ìpínlẹ̀ Anambra tí ṣetán látí kópa nínú eré ìdárayá tó ń bọ̀.

Comments are closed.

button