Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Nàìjíríà Kéde Ọjọ́ Kínní Oṣù Karùn-ún, Ọdún Yìí Fún Ìsinmi Àwọn Òṣìṣẹ́

Lekan Orenuga

146

Ìjọba Nàìjíríà tí kéde Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kínní oṣù kàrún, ọdún 2025 gẹ́gẹ́bí ọjọ́ ìsinmi fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ jákèjádò Orílẹ̀-èdè látí samisi Ayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn òṣìṣẹ́ tí ọdún yìí.

‎ Mínísítà fún ètò abẹ́lé, Dókítà Olubunmi Tunji-Ojo, tó ṣé ìkéde náà ní orúkọ Ìjọba Àpapọ̀ tún sọ pé o ṣé pàtàkì kí á gbá àlàáfíà láàyè látí ní ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbàsókè lórí ètò-ọrọ àjé.

‎ Dr. Tunji-Ojo gbóríyìn fún àwọn òṣìṣẹ́ fún ìtara wọn àti ìrúbọ wọn. O ṣé àkíyèsí pé àwọn akitiyan àwọn òṣìṣẹ́ àti ìbọ̀wọ̀ fún òfin àti àṣẹ ló ń gbé orílẹ̀-èdè náà gá jùlọ.

‎ L’àkókò tó nki àwọn òṣìṣẹ́ ní ayẹyẹ ayọ̀, Mínísítà náà rọ́ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ní ìrètí nínú ìṣàkóso tí Ààrẹ Bola Tinubu.

Comments are closed.

button