Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Kebbi Ti Gbáradì Fún Ìrìnàjò Hajj, Ọjọ́ Kẹsàn-ún Osù Karùn-ún Ní Àwọn Arìnrìnàjò Yóò Gbérasọ

56

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kebbi ti gbáradì láti kó àwọn arìnrìnàjò ẹgbẹ̀rún mẹ́ta lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ènìyàn lọ sí Orílẹ̀-èdè Saudi Arabi fún iṣẹ Hajj ti ọdún 2025

 

Adarí Ètò Hajj tí ó tún jẹ́ Emir Argungu, Alhaji Samaila Muhammadu Mera ni ó fi ọ̀rọ̀ léde wípé àwọn ìpín àkọ́kọ́ yóò gbéra láti pápákọ̀ òfurufú  àgbáyé Ahmadu Bello ní ọjọ́ kẹsàn-án osù karùn-ún ọdún 2025

 

Emir sàlàyé pé àwọn arìnrìnàjò yóò gba ẹ̀tọ́ wọn àtipé ètò tí ó gún régé ti wà láti rí i dájú pé owó sísẹ́ alti ìpààrọ̀ owó yóò lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀. Alhaji Mera gbósùbà fún Gómìnà Nasir látàrí àtìlẹ̀yìn rẹ̀ èyí tí ó mú kí àseyọri ńlá wáyé nínú ètò Hajj ọdún 2025

Comments are closed.

button