Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì ààrẹ Bẹ Ìpínlẹ̀ Delta Wò

138

 

Igbákejì ààrẹ Kashim Shettima ti gúnlẹ̀ sì ìlú Asaba tii ṣe Olú ìlú ìpínlẹ̀ Delta.

Ìrìn-àjò náà ní ṣe pẹ̀lú Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta, Governor Sheriff Oborevwori to dìgbà dẹrulù rẹ̀ lọ si ẹgbẹlẹ́ òṣèlú All Progresses Congress (APC), èyí tó gbàá lálejò.

Ọkọ̀ agbérapá Òfúrufú ààrẹ gbé igbákejì ààrẹ gunlẹ sì ìlú Asaba ní déédé aago mẹwàá ààbọ̀ o kọjá iṣẹ́jú méjì sí pápákọ̀ Òfúrufú
ìjọba àpapọ̀ ti gómìnà Sherrif Oborevwori sì lọ kíi káàbọ̀ àti fún ìgbàlejò.

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Abdullahi Ganduje, Gómìnà ìpínlẹ̀ Imo àti alága àjọ Progressive Governors’ Forum, Hope Uzodinma àti àwọn Gómìnà kan ní wọn ti dè silẹ láti alẹ́ ọjó Aiku fún ayẹyẹ máleègbàgbé náà.

Ẹgbẹ òṣèlú alátakò, People’s Democratic Party lo ti ń se àkóso ìpínlẹ̀ náà láti ìgbà tí wọn ti dáa sílẹ̀, ìgbà àkọ́kọ́ nìyí ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC yoo ṣàkóso bí gomina Oborevwori ṣe lọ kúrò ninú ẹgbẹ oṣelu tó wà tẹ́lẹ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button