Take a fresh look at your lifestyle.

Ìbò Ọdún 2027: Ọ̀dọ́ Yóò Sàtìlẹyìn Fún Ẹgbẹ́ SDP

118

Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ìlọsíwájú ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n n pè ní Alliance for Transformation Mandate (ATM), ti sọ pé àwọn yóò sàtìlẹyìn fún ẹgbẹ́ Social Democratic Party (SDP) látàrí ìbò àpapọ̀ ọdún 2027 tó ń bọ̀.

Ọ̀gá àgbà patapata ẹgbẹ́ náà, ọ̀gbẹ́ni Ebong Iyang ló sọ èyí pé òun lu adarí ẹgbẹ́ SDP lọ́gọ ẹnu lábẹ́ ìdarí alága apapọ wọn, ọ̀gbẹ́ni Shehu Gabam, àti pé òun fi asiko ti gba awon ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níyànjú pé kí wọn lọ darapọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ náà kí wọn leè gba Nàìjíríà là.

Ó wá pe Oludije ààrẹ nínú ìbò ọdún 2023 nínú ẹgbẹ́ SDP, ọ̀gbẹ́ni Adebayo Adewale pé ọ̀pọ̀ oloselu ń bọ̀ wá dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́. Àti pé,
ẹgbẹ́ Alliance for Transformation Mandate yóò ṣiṣẹ́ pọ̀ mọ́ àwọn ti ó yẹ kí wọ́n ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú láti mú ẹgbẹ́ Social Democratic Party dè èbúté ògo ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

“A tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹnikẹni ti inú bá ń bí fún àwọn ìgbésẹ̀ wọn yìí, sugbon ẹgbẹ́ ATM ń polongo àlàáfíà, àìsí jagidijagan ẹgbẹ́ -Social Democratic Party ni,” Ọ̀gá àgbà pátápátá fi èyí kun.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button