Take a fresh look at your lifestyle.

Tani Yóò Jáwé Olúborí Láàrín Al Ahly Àti Sundowns Nínú Ìdíje CAF

Lekan Orenuga

92

Al Ahly àti Mamelodi Sundowns tí ṣetán ìfẹ́sẹ́wọsẹ́ kán ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì ní pápá ìṣèré ‘Cairo International’ bí wọ́n tí n ja fún ayé níbi ìparí eré-ìdárayá tí ‘CAF Champions League.’

‎ Ìfẹ́sẹ́wọsẹ́ àkọkọ́ ní ‘Pretoria’ parí ní ọ̀mì, èyí tó ṣokunfa pé èyíkéyìí nínú ikọ méjèèjì ìfẹ́sẹ́wọsẹ́ ìkejì lé jamọ́ lọ́wọ́. Sùgbọ́n pẹlú ìtàn-àkọọlẹ tí Al Ahly nínú bọ́ọ̀lù afẹ́sẹgbá ilẹ̀ Áfíríkà, Sundowns ló ń bóri ìpàdé wọ́n nínú ìdíje náà ní àìpẹ yìí.

‎Sundowns kó tí pàdánù sí ọwọ́ Al Ahly nínú ìfẹ́sẹ́wọsẹ́ mẹ́jọ láti bí ọdún 2021 sẹyìn èyí tí Al Ahly náà ń gbèrò láti yí pàdà nínú ilé wọ́n.

‎Ẹ̀wẹ̀, Pyramids FC ati Orlando Pirates náà yóò figa gbágà láti mọ ìkọ Kejì tí yóò kópa nibi aṣe kagba ìdíje CAF Champions League lẹyìn tí àwọn náà gbá odo-odo (0-0) nínú ìfẹ́sẹ́wọsẹ́ wọ́n ní pápá ìṣèré FNB ní South Africa.

Comments are closed.

button