Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Katsina Gbóríyìn Fún Àwọn Ẹṣọ Aláàbò Òfurufú Ìwọ̀-oòrùn Àríwá ‎

Lekan Orenuga

85

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Katsina, Malam Dikko Umaru Radda, tí ṣé àbẹwò pàtàkì kán sí ẹgbẹ́ Àwọn Ológun òfurufú tó ń ṣiṣẹ́ nínú ètò ààbò tí wọ́n pé ní Fansan Yamma ní Katsina níbí tó tí ń yìn àwọn ipá wọ́n nínú iṣẹ́ ààbò tí ìwọ̀-oòrùn àríwá.

‎ L’àkókò ibẹwo náà, Gómìnà Radda ṣé àfihàn ìdùnnú rẹ̀ fún àwọn àṣeyọrí tí àwọn ọmọ ogun ofurufu ṣé ní àgbègbè náà láti kojú awọn Agbesunmọmi.

‎ Gómìnà náà tó tún jẹ́ Alága àwọn Gómìnà apá ìwọ̀òrùn àríwá, jẹrisi àwọn iṣẹ́ àwọn ọmọ ogún náà nítorí wípé àwọn onijagidijagan náà bẹrù wọ́n gidigidi.

‎ Nígbàtí o n dáhùn, Alàkóso tí àwọn ọmọ ogún fún iṣẹ́ àkànṣe náà, Air Commodore Ibrahim Garba Jibia ṣé àpèjúwe àbẹwò náà gẹ́gẹ́bí òun ìwúrí fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ológun náà, èyí tó tún ṣàfihàn ìpinnu Gómìnà náà sí ààbò àwọn aráàlú àti dukia wọ́n ní Ìpínlẹ̀ Katsina.

Comments are closed.

button