Gómìnà Ìpínlẹ̀ Adamawa, Ahmadu Fintiri, tí tún fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ sí látí ṣé àtìlẹ́yìn fún àwọn ilé-iṣẹ́ ìbílẹ̀ fún pàtàkì ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà àti Orílẹ̀-èdè lápapò.
Gómìnà sọ èyí dí mímọ̀ l’àkókò ayẹyẹ Ọjọ́ Ọdún àpapọ̀ Nnoma-Jhar ti 2025, tó wáyé ní Murum Mbula, Ìjọba Àgbègbè Demsa ní Ìpínlẹ̀ Adamawa.
Lati ẹnu Gómìnà èyí tí Kọmiṣọna fún Ìdàgbàsókè ìgbèríko ló ṣoju sọ, Gómìnà Fintiri rọ́ àwọn ènìyàn Mbula látí wà ní ìṣọ̀kan, kí wọ́n sí ṣé ojúṣe wọ́n fún ìlọsíwájú Ìpínlẹ̀ náà àti orílẹ-èdè.
Lára àwọn olóye tó wá níbẹ ní Gómìnà Ìpínlẹ̀ Bauchi, Bala Mohammed, ẹni tí wọ́n fí oyè ìbílẹ̀ Talaban Mbula dá lọla, tó túmọ sí “Ìmọ́lẹ̀ tí Mbula.”
Olórí ìbílẹ̀ náà àti àwọn tí ọrọ kán gbóríyìn fún Gómìnà Fintiri fún àtìlẹ́yìn ìtẹ̀síwájú tó ń ṣé fún igbelaugẹ àṣà ní Ìpínlẹ̀ Adamawa.
Comments are closed.