Take a fresh look at your lifestyle.

Wọ́n Sin Òkú Balógun Ikọ̀ Rangers Tẹ́lẹ̀ri, Isiadinso Ni Ìpínlẹ̀ Anambra

126

Wọ́n ti sin Òkú Balógun Ikọ̀ Rangers Intl FC ti Enugu tẹ́lẹ̀rí ní ọjó Ojoru ní ìlú rẹ, Obeagu Osili. Njikoka, ìjọba ibilẹ Anambra, ipinlẹ Anambra.

Agbabọ́ọ̀lù teleri náà ló jẹ balogun iko Rangers laarin odun 19811984, o ku ni ojo ketala, oṣù kẹta ọdún yìí ní ẹni ọdún merinlelogota.

Ní ibi iwasu eto isinku, oníwàásù Bísọ́ọ̀bú Emmanuel Okoro tó je alaga teleri àjọ Pentecostal Fellowship of Nigeria, ẹka ti Njikoka sọ pé, isinku náà jẹ ka rántí pé asan laye. O mú iwasu rẹ nínú Bíbélì ninu ìwé Ìfihàn, pé Ọ̀run ati Aye jẹ otitọ àti pé gbogbo ènìyàn lọkunrin ati lobinrin ní wọn yóò jabo iṣẹ ti wọn gbé ilé ayé ṣe lọdọ Ọlorun.

Ó wá gbàdúrà kí Olorun gba ọkàn oloogbe – Isiadinso náà. O wà pé àwọn tó ti wá laaye kí wọn fi ìbẹrù gbe ìgbé ayé wọn, kí wọn sì sìn ọmọnìyàn ní ọnà láti leè wọ ìjọba ọ̀run.

Ọgbẹni Augustine Igweokolo to jẹ alaga teleri agbábọ́ọ̀lù – Chairman, Ex Rangers Intl FC players, sọ pé ọgbẹni Isiadinso jẹ ènìyàn gidi àti ara ọtọ láwùjọ àti lórí pápá.

Ọgbẹni Igweokolo sọ pé oloogbe náà jẹ ogbontarigi agbaboolu ní ipò àárín tó ń dẹru ba àwọn alátakò wọn ní igbà ayé rẹ.

Pásítọ̀ sọ pé o dun oun pe iku mu ògbóntàrigì agbabọ́ọ̀lù lọ ní gúsù ìlà oòrùn, o wà pé àwọn ènìyàn àti àwọn ìjoba láti máà bù ọlá fún wọn nigba ti wọn bá ṣi wá laaye.

Lára àwọn ti wọn pejọ síbi isinku náà láti ri ; Oloye Joe Martins Uzodike, Sylvanus Okpala ti wọn máa sì Quicksilver, Victor Nwangwu, Arthur Ebunam, Harrison Okagbue, akọnimọọgba teleri Cranes of Uganda, Ben Ugwu (Surugede) abbl.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button