Take a fresh look at your lifestyle.

Wọ́n Dá Ọmọ Ẹgbẹ́ Ìgbìmọ̀ FIFA Tẹ́lẹ̀rí Sílẹ̀

139

Ọmọ ẹgbẹ́ igbimọ FIFA teleri. Mamoutou Toure ní wọn ti dá silẹ lẹ́wọ̀n ní Mali bayii lẹyin nǹkan bí ọdún Méjì ní àtìmọ́lé latari ìwà àjẹbánu bí àwọn oníròyìn Málì ṣe sọ ní ọjó Ọjọ́rú.

 

Ọgbẹni Touré tó jẹ ààrẹ àjọ eré Bọ́ọ̀lù ilélẹ̀ Málì láti ọdún 2019 ní wọ́n dá silẹ lọ́jọ́ Isegun leyin tó ti lo ọjó meji lé lógún le ẹgbẹta ní ẹwọn. O ṣíṣe pẹlu àjọ FIFA fún ọdún mẹrin, o fi ipo rẹ silẹ nigba ti o kùnà láti dije ninu idibo tuntun.

 

Ọmọ ọdún mẹta din láàdọ̀rún náà ní wọ́n gbamu ní oṣù kẹjọ ọdún 2023 pe o ṣe owó ìlú tó jẹ́ mílíọ̀nù mejidinlogbon Dọ́là makumaku sugbon ti ilé ẹjọ ilé Málì dá silẹ l’alafia latari awon nnkan kan bí iroyin ṣe roo.

 

Won fi ẹ̀sùn kan pe o wu iwa ti kò dára ni àkókò rẹ bí adari ẹ̀ka ti owó igbimọ ìjọba àpapọ láti ọdún 2013 sì 2019.

 

Ọgbẹni Touré ṣẹ́ gbogbo àwọn ẹ̀sùn wọnyi, wọn sì yàn sì ipò ààrẹ- Malian Football Federation president ní ìgbà kejì.

 

Nígbàtí o wà ní ẹ̀wọ̀n, o gba Lẹta aduroti láti ọwọ ààrẹ àjọ FIFA, Gianni Infantino. Sibẹsibẹ, Touré kò jẹ ọmọ ẹgbẹ́ àjọ igbimọ FIFA tàbí Confederation of African Football’s executive committee
mọ́.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button