Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Gombe Dunnú Pẹ̀lú Àwọn Onígbàgbọ́ Lásìkò Àjíǹde Olùgbàlà, Ó Pè Fún Ìfi Àdúrà Jagun

87

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Gombe, tí ó tún jẹ́ alága fún àwọn Gómìnà apá Àréwá, Muhammadu Inuwa Yahaya ti dáwọ̀ọ́ ìdùnnú pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ Jákè-jádò gbogbo àgbáyé lásìkò pọ̀pọ̀sìṣì àjíǹde olùgbàlà, ó wá gbàwọ́n níyànjú láti tẹ̀síwájú nínú ìfarajì, ìrètí àti ìfàdúràjagun

 

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àyájọ́ àjíǹde ti ọdún 2025, Gómìnà Yahaya sàfirinlẹ̀ pàtàkì àsìkò náà èyí tí ó sàfihàn ìfẹ́, ìsọ̀kan àti ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti ìfàrájì fún ọmọnìyàn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí Jesu olùgbàlà fi lélẹ̀

 

Ó wá sàfihàn ìgbàgbọ́ rẹ̀ pé ìbùkún àjídìde Jesu yóò se iranlọwọ fun idagbasoke Orilẹ-ede Naijiria

 

Comments are closed.

button