Take a fresh look at your lifestyle.

Àpérò Ẹlẹ́ẹ̀keje Ìgbìmọ̀ Àwọn Ọba Alayé Àréwá Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Gbérasọ

99

Látàrí bí wàhálà òhun ìdààmú àwọn alákatakítí Boko Haram se ń pọ̀ si ní apá Arewa Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, papàá jùlọ Ìpínlẹ̀ Borno àti Gúsù Ilà Oòrùn, ìgbìmọ̀ àwọn Ọba Alayé apá Arewa ti pe ìpè fún ìfikùnlukùn ẹlẹ́ẹ̀keje irú rẹ̀ èyí tí ó wáyé ní ìlu Maiduguri, Ìpínlẹ̀ Borno, ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun

 

Àkọmọ̀nà Àpérò náà ni “ Ààbò tí ó péye ní Ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ Ìdàgbàsókè àti ìtẹ̀síwájú Apá Àréwá”, gbogbo àwọn Emir apá Arewa, Alẹ́nulọ́rọ̀, Adarí Ẹ̀sọ́ Aláààbò, Abẹnugan-an nínú iṣẹ́ ìjọba ni ó péjú sí ibi ìpàdé náà níbi tí wọ́n ti ń fi ikùn-lukùn láti wá ojútùú sí wàhálà àìrajaja ètò àbò èyí tí ó ń wáyé ní àgbègbè náà

 

Ìpàdé náà wáyé látàrí bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno , Ọ̀jọ̀gbọ́n Bagbagana Umara Zulum ati Sheu ti Borno, Alayeluwa Abubakar Ibn Umar Garbai El-Kanemi se pariwo síta látàrí wàhálà tí ó ń wáyé ní àgbègbè náà

 

Comments are closed.

button