Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ké sí ọmọ Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà láti wá da okòwò sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nígbà tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ìpínlẹ̀ náà wà lójú iṣẹ́ lójúnà àti mú kí ọrọ̀ àjé gbèru síi nípasẹ̀ ètò ìgbáyé-gbádùn.
Makinde ló fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ nígbà tó n ṣí Abúlé fún ṣíṣe àkójọpọ̀ eré àgbéléwò (Film Village), eléyìí tí Òṣèré Kunle Afọlayan dá sílẹ̀ ní ìlú Igbojaye ní agbègbè Òkè Ogun, ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, (KAP Film Village & Resort).
Gómìnà fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó ṣàlàyé pé ṣíṣe àgbékalẹ̀ Abúlé yìí jẹ àṣeyọrí nlá fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti àfihàn wí pé èròngbà àti ìpinnu ìjọba láti fojú sun ẹka ìgbáyé-gbádùn ti n so èso rere.
Gómìnà wá kí Òṣèré Kunle Afolayan kú oriire fún iṣẹ́ àkànṣe náà, nígbà tó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun yóò sa ipá òun láti rí pé iṣẹ́ náà dúró.
Makinde wá paá laṣẹ fún Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìtẹ̀síwájú láti gun le àtúnṣe òpópónà Okaka sí Igbojaye (Okaka-Igbojaye Road) eléyìí tó lọ forí sọ Abúlé náà.
Bákan náà ni Gómìnà ṣèlérí láti pèsè ohun Àmúṣagbára eléyìí tí yóò máa lo agbára òòrùn, nígbà tó tún fi kún un pé òun yóò rí dájú pé ìjọba mú iná mọ̀nàmọ́ná láti ìlú Okaka lọ sí Abúlé náà.
Gómìnà wá fi àsìkò náà ké sí àwọn ọmọ bíbí àti olùgbé Orilẹ Èdè Nàìjíríà nílé àti lókè òkun láti wá dá okòwò sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nígbà tó tẹnu mọ́ pé ilẹ̀kùn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣí sílẹ̀ fún gbogbo ẹni tó bá ṣetán fún ìdókòwò.
Lara àwọn tó kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú Gómìnà ní Komisana y Àṣà àti Ìgbáyé-gbádùn, Ọ̀mọ̀wé Wasiu Olatunbosun; Komisana fún Ìròyìn, Omo-oba Dọtun Oyelade; Komisana fún ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ àti eré Ìdárayá, Wasilat Adegoke; àti àwọn míràn tó wà nínú ìgbìmò aláṣẹ Gómìnà.
Abiola Olowe
Ìbàdàn