Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà lókè òkun yan àwọn aláṣẹ tuntun
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà lápapọ̀ lókè òkun ti yan àwọn aláṣẹ tuntun tó pinnu láti jẹ́ aṣojú rere fún Nàìjíríà.
Aarẹ ẹgbẹ naa Ọgbẹni Juwon Fayomi, ṣe ipinnu yii nibi ayẹyẹ ifilọlẹ ati Idanilẹkọ fun gbogbogboo ọdun 2025 ti ẹgbẹ́ náà.
O sọ pe awọn akẹkọ Naijiria to ju miliọnu meji ati aabọ lọ to wa loke okun yoo tunbọ maa kopa ninu idagbasoke Naijiria.
“Idagbasoke orilẹ-ede Naijiria di ohun aa gbaruku mọ”.
Ẹlẹgbẹ́ Fayomi pinnu titẹsiwaju lori ajọṣepọ pẹlu NANS ti Naijiria lori igbe aye irọrun fun awọn akekọọ Naijiria.
O tun wa ṣe ipinnu fun ọpọlọpọ agbekalẹ idagbesoke lasiko rẹ.
Ẹni ti o jẹ Baba fun ayẹyẹ naa, Ọgbẹni Samuel Ikechukwu Asadu wa gboriyin fun Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà lápapọ̀ lókè òkun fun bi wọn ṣe jẹ arimuyangan fun orilẹ-ede.
O wa gba wọn niyanju lati ma farasin lori kikopa ti wọn si ibuyikun Naijiria ni oniruuruu orilẹ-ede ti wọn ba wa.
Eyi lo larinrin julọ ninu ayẹyẹ naa ibura fun awọn aláṣẹ tuntun lati orisirisi orilẹ-ede lasiko kannaa.