Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Taraba: Obìnrin Àkọ́kọ́ Yóò Ṣe Àgbékalẹ̀ Ilé Ìwòsàn Alágbèéká

169

Obìnrin àkọkọ, Sẹ́nétọ̀ Oluremi Tinubu ti ṣe ileri láti fún ìjọba ìpínlẹ̀ Taraba ní Ilé Ìwòsàn Alágbèéká látàrí ètò ìjọ̀ba-ìrètí ọtun, Renewed Hope Initiative, RHI.

Ó sọ eyi ní Jalingo níbi ìfilọ́lẹ̀ Ilé Ìwòsàn Alágbèéká àti ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́
ti ìjọba ìpínlẹ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ.

Ó gbósùbà fún ìjọba ìpínlẹ̀ Taraba fún jíjẹ kí ètò ìlera sáájú ètò gbogbo rẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ pàápàjùlọ ni agbègbè ti wọn àwọn ènìyàn kò fọkàn sí.

Ìyáàfin Tinubu sọ pé ìrètí wà pé afi6kun ilé ìwòsàn Alágbèéká yóò ràn ìjọba lọ́wọ́ láti tètè ṣe ètò ìlera fún àwọn mẹ̀kúnnùn tó wà ní ìgbèríko ní àkókò pàjáwìrì.

Ìyáàfin Tinubu lu ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tuntun fún akékọ̀ọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ti wọn ń ṣe ní ọ̀gọ ẹnu pé o jẹ ìgbésẹ tó dára, yóò da àwọn ogo wẹẹrẹ tó ti sá kúrò ní ilé-ìwé padà káàkiri Nàìjíríà.

Ayeyẹ Ìfilọ́lẹ̀ náà jẹ ọkan lára ayẹyẹ àbẹwò Ọlọ́jọ́ Méjì aya ààrẹ sì ipinlẹ náà.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button