Ìrìnàjò Hajj Ọdún 2025: Ìgbìmọ̀ Alálàájì Ìlú Abuja Ti Bẹ̀rẹ̀ Àyẹ̀wò Ìlera Fún Àwọn Arìnrìnàjò
Ìgbìmọ̀ Alálàájì ẹka ti Abuja ti kéde ìbẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ìlera fún àwọn tí ó ń gbèrò láti rin ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ Saudi Arabia ní ọdún 2025
Nínú ọ̀rò kan tí ó fi léde láti ẹnu olùfọ̀rọ̀léde àjọ náà, Ahmed Saleh, èyi tí ó sàfihàn rẹ̀ sí àwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Abuja. Ó sàfirinlẹ̀ àyẹ̀wò pàtàkì náà èyí tí yóò wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kejìlá osù kẹrin àti ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹtàlá osù kẹrin ọdún 2025 ní ọ́ọ́fìsì ìgbìmọ̀ àjọ náà èyí tí ó wà ní Bassan Jiwa, ní ẹ̀bá pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Azikwe, Abuja, tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní déédé agogo mẹ́sàn-an òwúrọ̀
Ó gba àwọn tí ó ń gbèrò láti rin ìrìnàjò Hajj naa níyànjú láti péjú sí ibi àyẹ̀wò náà pẹ̀lú ẹ̀rí owó sísan, nítorí pé ètò náà se kókó.