Ariwo Ayọ̀: Àjọ Ọlọ́pàá Gba Ìtúsílẹ̀ Ènìyàn Mẹ́tàdínlógún Tí Ó Wà Ní Ìgbèkùn Àwọn Ajínigbé
Àjọ Ọlọ́pàá Ẹka ti Ìpínlẹ̀ Kaduna pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọ́ọ́fìsì àpapọ̀ ti olùbádámọ̀ràn lórí Ètò Àbò ti gba ìtúsílẹ̀ ènìyàn mẹtádínlógún tí ó wà ní ìgbèkùn àwọn ajínigbé, èyí tí wọ́n ti wà ní àhámọ́ láti ọjọ́ kẹta, osù kẹta, ọdún 2025, ní àgbègbè Sarkin Pawa, Ìpínlẹ̀ Niger
Agbẹnusọ àjọ náà, Muyiwa Adejọbi ni ó síṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ọ́ọ́fìsì àpapọ̀ Àjọ Ọlọ́pàá, ní ìlú Abuja
Adejobi sọ pé àjọ náà ti ní àseyọrí ńlá látàrí ìgbìyànjú àti ìlàkààkà rẹ̀ láti dóòlà ẹ̀mí ará ìlú èyí tí ó wáyé láìpẹ́ ní ìlú Kaduna. Àtipé ìwádìí ń tẹ̀síwájú láti rí i dájú pé gbogbo àwọn tí ó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ láabi náà ní yóò fi imú kó ata òfin