Ààrẹ Orílẹ̀-èdè South Sudan, Salva Kiir ti yọ Minisita Ilẹ̀ Òkèèrè, Ramadan Mohamed nípò, ó yan igbákejì rẹ̀ Monday Simaya Kumba gẹ́gẹ́ bí mínísítà tuntun fún ilẹ̀ òkèèrè èyí tí ó wáyé ní Ọjọ́rú
Kò sí ìfiléde ìdí kan ní pàtó fún ìyọnípò náà sùgbọ́n ó se é ṣe kí ó wáyé látàrí òfin ìwọlé-wọ̀de tí Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà se
Awuye-wuye náà wáyé látàrí kíkùnà láti gba ọmọ Orílẹ̀-èdè Congo tí Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lé jáde, látàrí ìsesí náà Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dún ìkookò láti gba ìwé ìgbélùú àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè South Sudan
Títí di àsìkò yìí, ìjọba kò ì tí ì sọ̀rọ̀ lórí ìyọnípò náà bóyá látàrí àtúntò tàbí awuye-wuye pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà