Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Àti Saudi Arabia Gbé Ìgbésẹ̀ Akin Láti Gbógunti Gbígbé Òògùn Olóró
Àjọ NDLEA àti ojúgbà rẹ̀ ti Orílẹ̀-èdè Saudi Arabia, GDNC ti buwọ́lu ìwé àdéhùn pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láti gbógunti gbígbé òògùn olóró àti àsìlò òògùn
Lára àdéhùn àjọ méjéèjì náà ní ìran-ara-ẹni lọ́wọ́ nípa pípèsè ohun èlò tí ó péye, ìdánilẹ́kọ̀ọ́, ìwádìí tí ó péye àti ìfunilára nípa àwọn òbìlẹ̀lẹ́
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lásìkò ayẹyẹ ìbuwọ́lu ìwé àdéhùn náà ní ìlú Riyadh, Ọ̀gá Àgbà Àjọ NDLEA ti Orilẹ-ede Naijiria, Ọ̀gágun Mohammed Buba Marwa, ó sàfihàn ìbásepọ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́ láàrin Orílẹ̀-èdè Naijiria ati Saudi Arabia
Ó sàfirinlẹ̀ wàhálà àsìlò òògún ní Orilẹ-ede agbaye gbogbo, ó wá pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láti gbógunti ìwà burúkú náà