Kọmísọ́nà Fún Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin Àti Ìdàgbàsókè Àwùjọ, Arábìnrin Fatimah Momoh ti nawọ́ àánú léyìí tí ó se ìrànlọ́wọ́ fún Arábìnrin Soje Ogori, tí ó jẹ́ olùgbé Ogori-Magongo, ẹni tí iná jó ilé rẹ̀ ní àìpẹ́
Nígbà tí ó se àbẹ̀wò sí àyè náà ní ọjọ́ Ajé, Kọmísọ́nà fi àwọn ohun èlò atunilára bí i ibùsùn, oúnjẹ àti owó ta àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn lọ́rẹ
Ó tẹ̀síwájú pé ìgbésẹ̀ náà wà ní ìbámu pẹ̀lú èròńgbà ìjọba Ìpínlẹ̀ Kogi láti mú ìdàgbàsókè bá ará ìlú àti láti ran àwọn tí ó kù díẹ̀ kààtó fún lọ́wọ́ láwùjọ