Take a fresh look at your lifestyle.

Ìṣèjọba Mi Koni Tojú Bọ Ìlànà Yíyan Ọmọ Oyè – Makinde

175

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde tí jẹ ko fi mímọ̀ pé ìṣèjọba òun yóò tẹ síwájú láti máa tẹlé ìlànà tó tọ nínú ìṣàkóso Ìpínlẹ̀ náà

Bákan náà ló ṣàlàyé pé ìṣèjọba òun kò ní tojú bọ ọba jíjẹ àti ìlànà yíyan ọmọ oyè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Gómìnà Makinde lo síṣọ lójú ọ̀rọ̀ yìí níbi ayẹyẹ iwuye Ọba Abdulakeem Abímbólá Owoade I gẹ́gẹ́ bíi Aláàfin Ìlú Ọ̀yọ́ Kẹrìndínlàádọta (46), ètò to wáyé ni Ilé Ẹkọ Olivet Baptist ní ìlú Ọ̀yọ́.

Makinde fi bí Ọba Abímbólá ṣe gorí itẹ gẹ́gẹ́ bíi Aláàfin ṣe àpèjúwe àmúlò ìlànà tó tọ nínú ìṣàkóso rẹ̀ àti ọkàn ìfaradà àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀yọ́.

Gómìnà wá ké sí Ọba Owoade láti ṣiṣẹ takuntakun lójúnà àti mú ìlọsíwájú dé bá ìlú Ọ̀yọ́, nígbà tó fi àsìkò náà mú dá gbogbo àwọn ènìyàn Ìlú Ọ̀yọ́ lójú pe Ìjọba yóò tubọ máa tẹ síwájú láti kó ipa tó ṣe kókó nínú ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti mú ìgbéga dé bá ọdún Sango gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan lára Àṣà àjogúnbá lágbayé.

Bẹẹ náà ni Makinde fi àsìkò náà gbà àwọn tó n tako ìyànsípò Aláàfin tuntun náà ni ilé ẹjọ́ níyànjú láti gbà Ọba Owoade gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí Ọlọrun yàn, ti àwọn ènìyàn àti ìjọba náà sì fọwọ́ sí.

Bákan náà ló fi àsìkò náà ké sí Kabiyesi àti àwọn Ọ̀yọ́mèsì lati ṣiṣẹ́ láti ri dájú pé wọn kò yẹ̀ kúrò lójú ìlànà yíyan ọmọ oyè, nígbà tó rawọ́ ẹbẹ sí wọn pé kí wọn rí dájú pé irúfẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ látẹ̀yìn wá kò tún wáyé mọ́.

Ṣáájú ni ẹni tó ṣojú Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu, Mínísítà fún ohun Àmúṣagbára, Olóyè Bayo Adelabu kí Ọba Owoade ki oríire, nígbà tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Itẹ Aláàfin jẹ́ àmì ìgbélárugẹ àṣà, ìṣọ̀kan àti ogún ìlú tó lágbára jù lórí ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀, Akọwe Ìjọba, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olanike Adeyemo, ẹni tí Komisana fún Ìjọba Ìbílẹ̀ àti Òye jíjẹ, Abímbólá Ojo ṣojú fún ṣàlàyé pé iwuye Ọba Owoade ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ tó lààmì-laaka.
Adeyemo wá lu Gómìnà Makinde lọgọ ẹnu fún bí o ṣe gbé àṣà àjogúnbá lágbayé larugẹ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà tó ke sí gbogbo olùgbé Ìpínlẹ̀ náà láti rí ọjọ́ oni gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ayẹyẹ ìṣọ̀kan àti àṣà tó níye lórí.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Aṣòfin Monsurat Sunmoni to ti fi ìgbà kan rí jẹ́ Adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi àsìkò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ọmọ ìlú Ọ̀yọ́ lọkunrin àti lobirin, gbogbo ọmọ ilẹ̀ Yorùbá àti Gómìnà Makinde fún ọgbọn àtinuda to lo láti ri dájú pé ìlú Ọ̀yọ́ ni Aláàfin tuntun. O wá ṣèlérí pé àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀yọ́ yóò gbaruku ti Ọba Owoade lójúnà àti mú ìgbéga dé bá ìlú náà.

Bákan náà ni Aṣòfin to n ṣojú Ẹkùn àárín gbùngbùn Ọ̀yọ́, Aṣòfin Yunus Akíntúndé mu wá sí ìrántí gbogbo àwọn tó péjú síbẹ̀ pé o ti to ọdún Mẹrinlelaadọta (54) sẹ́yìn ti irú ayẹyẹ bayi ti wáyé ní Ìlú Ọ̀yọ́. Òun náà wà fi dá Oba Owoade lójú pé àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀yọ́ yóò kún lọ́wọ́ láti gbe ilu Ọ̀yọ́ gòkè àgbà

Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ, Ọba Owoade dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Makinde fún àtìlẹ́yìn rẹ̀, nígbà tó tún fi àsìkò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ọmọ bíbí ìlú Ọ̀yọ́ nílé ati lókè òkun fún àtìlẹ́yìn wọn, ìgbàgbọ ti won ni nínú rẹ̀ láti gun orí Àpèrè àwọn baba nla rẹ̀.
Ọba Owoade wa pe fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan lójúnà àti kojú àwọn ìpèníjà, eléyìí tí yóò mú kí ìdàgbàsókè àti ìmúgbòòrò dé bá ọrọ̀ ajé ìlú Ọ̀yọ́ ati Ipinle Ọ̀yọ́ lápapọ̀.

Lára àwọn tó péjú síbi ayẹyẹ náà ni aṣojú àwọn Gómìnà Ọ̀ṣun àti Òndó, ìyàwó Gómìnà Seyi Makinde, àwọn ládé-ládé àti lóyè-lóyè jákèjádò Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà àti àwọn èèkàn míràn.

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Comments are closed.

button