Àjọ Akpoazaa ti se ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kànlá ní Ìpínlẹ̀ Anambra lójúnà àti se àtìlẹyìn fún ètò ẹ̀kọ́ èyí tí yóò fún wọn ní ànfààní ètò ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro
Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ náà wáyé níbi ayẹyẹ tí ó wáyé ní Uhudim Uhuobo, Okija, ìjọba Ìbílẹ̀ Ihiala
Lára àwọn tí ó jẹ ànfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ náà ni méjì nínú àwọn akẹkọọ onípele kejì, ti mẹ́sàn-án yókù sì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ onípele àkọ́kọ́
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ètò náà, alákòsóo Àjọ Akpoazaa, Ọ̀mọ̀wé Frank Igbojindu sàfirinlẹ̀ pàtàkì ètò ẹ̀kọ́ àti ipa tí ó ní nínú ìgbé ayé àwọn ọ̀dọ́ àti ọjọ́ iwájú Orílẹ̀-èdè