Ìyàwó Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Oluremi Tinubu ti rọ àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ṣe Ìrànlọ́wọ́ àti àtìlẹ́yìn fún àwọn ènìyàn tó bá ní àìsàn Autism.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ láti sààmì sí ayẹyẹ ayajọ àìsàn náà ni o ti rawọ ẹ̀bẹ̀ láti rí wí pé àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ìmọ̀ lori àìsàn náà kí wọn ṣe àtìlẹ́yìn
Ìyàwó Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni inú oun ko dùn rárá sí àwọn ti o n fi àlàfo sile láàrin àwọn ènìyàn tó ni àìsán náà
Ó ní àìsàn náà ni ṣe pẹ̀lú ọpọlọ o ni fún ìdí èyí àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè gbọdọ ní sùúrù gidigidi fún àwọn tó bá ní àìsàn náà láti leè jẹ kí wọn tètè pada sí ipò.