Makinde Ni Okòwò Ti Fẹṣẹ Múlẹ̀ Ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Bí Ladoja, Igbákejì Gómìnà Àti Àwọn Aṣòfin Kan Ṣe Ṣe Àbẹ̀wò Síi Lẹ́yìn Ádùrá Eid.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti sọ di mímọ̀ pé ìṣèjọba òun ti dé ìpele eléyìí to fihàn pé okòwò ti rẹ́sẹ̀ walẹ̀ pẹ̀lú sisan owó tí kò dín ní Bílíọ̀nù Mẹrinlelogun (N24b) gẹ́gẹ́ bíi owó oṣù òṣìṣẹ́ ni Ìpínlẹ̀ àti Ìjọba Ìbílẹ̀.
Bákan náà ni Makinde tun fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìgbìyànjú ìṣèjọba òun lati mú kí okòwò gberu síi ti n so èso rere latari bi àwọn ilé iṣẹ́ olókoòwò aladaani se n ri àyíká tó rọrùn láti dá ilé iṣẹ́ sílẹ̀ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Gómìnà ló sọ ọ̀rọ̀ yii lásìkò tí àwọn Mùsùlùmí òdodo nínú èyí tí a ti ri àwọn tó di ipò òṣèlú mú ni ìjọba Àpapọ̀, Ìpínlẹ̀ àti ìjọba Ìbílẹ̀ ṣe ṣe àbẹ̀wò síi ni ilé rẹ̀ to wà ni agbègbè Ikolaba lẹ́yìn ti wọ́n kúrò ni Eid ti wọ́n ti lọ gbàdúrà òpin Ramadan ọdún yìí.
Nígbà tó n ba àwọn ènìyàn tó wá sí ilé rẹ̀ sọrọ, Gómìnà fi àsìkò náà kí gbogbo wọn fún àṣeyọrí oṣù Ramadan ti ọdún yìí, Makinde tún lù wọ́n lọgọ ẹnu fún ádùrá wọn, ìfọmọnìyàn ṣe, ìfarajìn àti àtìlẹ́yìn wọn fún ìṣèjọba rẹ̀, nígbà tó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, okòwò tó rẹ́sẹ̀ walẹ̀ kò ṣẹ̀yìn Ìbágbépọ̀ àlàáfíà tó jọba láàrin àwọn ẹlẹsin ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Makinde fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìjọba ti lọ ṣe àbẹ̀wò sí ìgbèríko Ijaiye eléyìí tó ní ilẹ̀ ti kò dín ni Ẹgbẹ̀rún Mẹtadinlọgbọn Sarè (27,000 hectares) nínú èyí tí Ìjọba ti rawọ́ ẹbẹ sí àwọn ènìyàn ìgbèríko náà láti yọnda Sarè Mẹ́ta (3 hectares) fún ìdásílẹ̀ ọjà àgbẹ̀ (Farmer’s Wholesale Market) eléyìí tí ìjọba n fojú sun láti dá sílẹ̀.
Bákan náà ni Gómìnà Makinde fi àsìkò náà ké sí àwọn tó di ipò òṣèlú kan tàbí òmíràn mú láti sa ipá wọn ki wọn ṣe ohun tó tọ nitori ìgbà àti àsìkò eléyìí to n pe gbogbo ọmọ Orilẹ Èdè Nàìjíríà níjà.
Nígbà tó n bá àwọn oníròyìn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọ̀rọ̀, igbákejì Gómìnà, Bayo Lawal gba gbogbo mùsùlùmí òdodo níyànjú láti ṣe àmúlò ẹkọ ikaanu, ìfẹ́ àti ìṣoore ti wọn ka nínú Qurani. O wá lu Gómìnà lọ́gọ ẹnu fún iṣẹ́ takun-takun to n ṣe pàápàá jùlọ nípa sisan owó oṣù òṣìṣẹ́ déédéé.
Ọjọgbọn Oloso wa fi àsìkò náà gbà Ádùrá pàtàkì fún Gómìnà ki ìṣèjọba rẹ̀ lè ṣe àṣeyọrí. O sí tun dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún atilẹyin rẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Lara àwọn tó ṣe àbẹ̀wò náà ní a ti rí: Ìgbákejì Gómìnà, Bayo Lawal, tó léwájú àwọn ènìyàn náà; Ọtun Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn, Aṣòfin Rashidi Ladoja; Aṣòfin to n sójú Gúsù Ọ̀yọ́, Olóyè Sharafadeen Allí; Ẹni to ti fi ìgbà kan rí jẹ́ igbákejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Ìgbákejì Alága ẹgbẹ́ PDP, Taofeek Arapaja; Ọjọgbọn Kamil Oloso; Igbákejì Adari Ile Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Mohammed Fadeyi; Oloye Nureni Akanbi, ati àwọn Alága ìjọba ìbílẹ̀ l’ọkunrin ati l’obinrin.
Abiola Olowe
Ìbàdàn