Ìjọba Ìpínlẹ̀ Katsina ti kéde ìpapòdà ìyá Gómìnà Dikko Umaru Radda, Hajjiya Safarau Umaru Baribari
Hajiyya Safara’u dágbére fáye ní òru àná ní ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́ọ́run. Ó jẹ́ akíkanjú obìnrin, ọ̀jọ̀gbọ́n àti aláànúú ènìyàn lásìkò ìsẹ̀mí ayé rẹ̀. Olùfọ̀rọ̀léde fún gómìnà, Ibrahim Kaulaha ni ó fi ìdì ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀
Kauhala tẹ̀síwájú pé yátọ̀ sí pé ó jẹ́ ìyá gómìnà Radda, Hajjiya Safara’u ti se ìtọ̀jù, àtìlẹ̀yìn fún àwọn olórí , èèkàn ìlú, tí wọ́n darí àwùjọ
Lára àwọn ọmọ ti olóògbé náà fi sílẹ̀ ní alákòsóo ìlú Radda, Alhaji Kabir Umar Radda, Hajiya Hauwa Umar Radda tí ó jẹ́ aya ààrẹ tẹ́lẹ̀rí tí ó di olóògbé, Umaru Musa Yar’adua