Take a fresh look at your lifestyle.

DR Congo, Rwanda Pè Fún Ìdáwọ́ Ogun Dúró

155

Ààrẹ orílẹ̀-èdè olómìnira Congo, Félix Tshisekedi àti ti orílẹ̀-èdè Rwanda, Paul Kagame ti pè ipe ìdáwọ́ogun dúró ní ìlà oòrùn DR Congo ní kíámọ́sá lẹ́yìn ìpàdé wọn tó wáyé ní Qatar.

Ó jẹ ìgbà àkọkọ ti àwọn olórí méjèèjì náà yòo se ìpàdé pọ̀ lẹ́yìn ti ikọ̀ ọlọtẹ M23 ti ilẹ̀ Rwanda sàtìlẹyìn fún gbọ́wọ́ ìjà sókè ní kíkan ní agbègbè náà, níbi ti ènìyàn bíi ẹgbẹ̀rún méje ti filẹ̀ sasọ bora láti oṣù kínní ọdún yìí.

Kòtíì yéni bóyá ikọ̀ ọmọ ogún M23 yóò dáwọ́ ogún duro lẹ́yìn tí ikọ̀ náà ti kùnà láti wá síbi ìpàdé àlàáfíà tó wáyé ní Angola ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun.

Ìpàdé àwọn olórí méjèèjì wáyé ní ọnà láti jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàrin àwọn ijọba DR Congo àti Ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ M23 wà papọ̀ lẹ́yìn ti ìpàdé àlàáfíà ti fori sọ́pán. Ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ sọ pé àwọn kò sè mọ̀ ní ọjọ́ Ajé lẹ́yìn ti àjọ European Union ti gbé òté lé ìdarí wọn.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button