Alẹ́nulọ́rọ̀ kan nínú ẹgbẹ́ òsèlú LP ẹka ìpínlẹ̀ Ebonyi, Ọ̀mọ̀wé Emmanuel Ezeh ti sàpèjúwe gómìnà Ìpínlẹ̀ Ebonyi tẹ́lẹ̀rí tí ó tún jẹ́ mínísítà fún àkànṣé iṣẹ́, Onímọ̀-ẹ̀rọ David Umahi gẹ́gẹ́ bí mínísítà tí ó ń síṣẹ jùlọ nínú ìsèjọba ààrẹ Tinubu
Ọ̀mọ̀wé Ezeh sọ ọ̀rọ̀ náà ní ìlú Abakaliki, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ebonyi nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nípa àmì ẹ̀yẹ tí àjọ Sliverbird fún-un gẹ́gẹ́ bí i mínísítà tí ó peregedé jùlọ nínú ìsèjọba tí ó ń lọ lọ́wọ́
Ezeh wá pàrọwà sí gómìnà ìpínlẹ̀ Ebonyi, Francis Nwifuru láti wo irúfẹ́ àwòkọ́sẹ rere náà fún ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Ebonyi